Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 99: Aájìn Jìn, Orú Mímọ́

Silent Night, Holy Night

Aájìn jìn, orú mímọ́,
'Pa rọ̀rọ̀, 'dára yà;
Yí wúńdíá, ìyá Krístì ká!
Ọmọ ọwọ́ mímọ́, jòjòlò
Sùn nínú àlàáfíà,
Sùn nínú àlàáfíà.

Aájìn jìn, orú mímọ́,
'Mọ́lẹ̀ dé, oòkùn sá;
Olùṣ'àgùtàn gbọ́ orin áńgẹ́l'
Kàbíyèsí a k' Ọba!
A bí Kríst' Olùgbàlà,
A bí Kríst' Olùgbàlà.

Aájìn jìn, orú mímọ́,
'Ràwọ̀ ọ̀run tàn 'mọ́lẹ̀
'Mọ́lẹ̀ dídàn lát' ojú Rẹ,
L' ó kún f' oòr' ọ̀fẹ́ ìgbàlà
Nígbàtí a bí Jésù,
Nígbàtí a bí Jésù.

Aájìn jìn, orú mímọ́,
'Ràwọ̀ ọ̀run tàn 'mọ́lẹ̀
K' á b' àwọn áńgẹ́l' kọrin,
Alelúyà s' Ọba wa,
A bí Kríst' Olùgbàlà,
A bí Kríst' Olùgbàlà.