Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 98: Lọ Kédé Rẹ̀ L' Or' Òkè

Go Tell it on the Mountain

Lọ kédé rẹ̀ l' or' òkè,
Ní gbangba àt' ibi gbogbo;
Lọ, kédé rẹ̀ l' or' òkè,
P' á bí Jésù Krístì.

Gbà wọn Olùṣ'àgùtàn,
Ń ṣọ́ àgbò wọn l' órù;
Wò ó l' ojú sánmọ̀ l' òkè
Ìmọ́lẹ̀ yọ sí wọn.

Lọ kédé rẹ̀ l' or' òkè,
Ní gbangba àt' ibi gbogbo;
Lọ, kédé rẹ̀ l' or' òkè,
P' á bí Jésù Krístì.

Ẹ̀rù b' Olùṣ'àgùtàn,
Gbà wọn gbọ́ orin 'yìn
T' àwọn ogun ọ̀run ń kọ.
Wọn ń kí Jésù k' àbò.

Lọ kédé rẹ̀ l' or' òkè,
Ní gbangba àt' ibi gbogbo;
Lọ, kédé rẹ̀ l' or' òkè,
P' á bí Jésù Krístì.

Níbẹ̀, ni 'bùjẹ ẹran,
L' á bí Jésù Krístì;
T' ó mú 'gbàlà wa fún wa,
L' oòrọ̀ 'jọ́ 'bí Ọba.

Lọ kédé rẹ̀ l' or' òkè,
Ní gbangba àt' ibi gbogbo;
Lọ, kédé rẹ̀ l' or' òkè,
P' á bí Jésù Krístì.