Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 97: Orin Ayọ̀ Ìbí Krístì

The First Noel

Orin ayọ̀ ìbí Krístì,
L' áńgẹ́l' kọ́kọ́ kọ s' Olùṣ'àgùtàn
'Nú papa n' bi wọn ń ṣọ́ àgbò wọn
L' órù 'ganjọ t' ó tútù fẹ́ẹ́rẹ́.

Orin ayọ̀, orin ayọ̀,
A bí Ọba Ísráẹ́lì.

Wọn w' òkè, wọn rí 'ràwọ̀ kan
T' ó ń dàn l' òkèèrè, n' ìlà oòrùn
Ó tàn ìmọ́lẹ̀ nlá s' orí ayé
Bẹ́ẹ̀ l' ó ń tàn l' ọ̀sán àti l' órù.

Orin ayọ̀, orin ayọ̀,
A bí Ọba Ísráẹ́lì.

Ìtànsán 'mọ́lẹ̀ 'ràwọ̀ náà
Tọ́ àmọ̀yè mẹ́ta s' ọ̀nà
Ibi tí a bí Ọba kan sí
Wọn ń tẹ̀lé ìràwọ̀ náà layé.

Orin ayọ̀, orin ayọ̀,
A bí Ọba Ísráẹ́lì.

Ìràwọ̀ yìí tẹ̀ síwájú
Títí ó fi dé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù,
N' bẹ̀ l' ó dúró t' ó sì sìmí
L' or' ibi tí a bí Jésù sí.

Orin ayọ̀, orin ayọ̀,
A bí Ọba Ísráẹ́lì.

Bẹ́ẹ̀ l' àwọn àmọ̀yè mẹ́ta,
Wolé n' ìrẹ̀lè s' ọ̀dọ̀ Jésù;
Wọn sì tú àpò ẹ̀bùn wọn,
Wúrà, tùràrí àt' ọjìá.

Orin ayọ̀, orin ayọ̀,
A bí Ọba Ísráẹ́lì.