Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 95: Nígbà Kan N' Ìlú Dáfídì
Once in Royal David's City
Nígbà kan n' ìlú Dáfídì
Ni ilé ẹran kan wà,
Níb' ìyá kan tẹ 'Mọ Rẹ sí;
Bùjẹ ẹran l' ẹni Rẹ;
María ni ìyá ná à,
Jésù Krístì l' Ọmọ rẹ.
Ó sọ kalẹ̀ lát' ọ̀run wá,
Ọlọ́run ohun gbogbo,
Ilé Rẹ ni ilé ẹran,
Búsùn ẹran l' ẹni Rẹ;
Àwọn òtòṣì lásán
Ni Jésù bá gbé l' ayé.
Ní ìgbà ọmọdé Jésù
A máa gbọ́rọ̀ ìyá Rẹ,
Ó fẹ́ràn Ó sì ń tẹríba
Fún ìyá; tí ń gbé E lọ́wọ́
Ó yẹ k' ọm' onìgbàgbọ́
Jẹ́ olùgbọ́ràn bí Rẹ.
Ojú wa yóò rí i n' ìkẹyìn
Nípa 'fẹ́ ràpadà Rẹ;
Nítorí ọmọ rere ni
Jẹ́ Olúwa lát' ọ̀run;
Òun yóò tọ́ àwọn 'mọ Rẹ
Síbi tí òun pàápàá lọ.