Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 94: Ayọ̀ F' Ayé, Olúwa Ń Bọ̀!
Joy to the World, the Lord is Come
Ayọ̀ f' ayé, Olúwa ń bọ̀!
K' ayé gbà Ọba rẹ̀;
Kí gbogbo wa fi àyè fún Un
K' àwọn ọ̀run kọrin.
K' àwọn ọ̀run kọrin.
K' àwọn, k' àwọn ọ̀run kọrin.
Ayọ̀ f' ayé, Jésù jọba!
K' àwọn èèyàn kọrin
Kí pẹ̀tẹ́lẹ̀ àti òkè,
Sì kọrin ayọ̀ wọn,
Sì kọrin ayọ̀ wọn,
Sì kọrin, sì kọrin ayọ̀ wọn.
Kò ní s' ẹ̀ṣẹ̀ àt' ẹ̀dùn mọ́,
Kò ní sí ègún mọ́;
Ó dé láti tàn 'bùkún Rẹ
Ká 'bi t' ègún náà dé
Ká 'bi t' ègún náà dé
Ká 'bi, ká 'bi t' ègún náà dé.
Òun Ó f' oòr'-ọ̀fẹ́ ṣàkóso,
Láti mú k' ayé mọ̀
Àwọn ògo ododo Rẹ
Àt' ìyànu 'fẹ́ Rẹ
Àt' ìyànu 'fẹ́ Rẹ
Àti, àt' ìyànu 'fẹ́ Rẹ.