Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 93: B' Àwọn Ara Ìgbàaní Ti F' Ayọ̀ Rí 'Ràwọ̀ Náà
As with Gladness Men of Old
B' àwọn ara ìgbàaní
Ti f' ayọ̀ rí 'ràwọ̀ náà,
Bí wọn ti f' inú dídùn
Tẹ̀lé 'mọ́lẹ̀ dídàn rẹ̀
Bẹ́ẹ̀ Olúwa Olóore,
Ni k' á mú wa d' ọ̀dọ̀ Rẹ.
Bí wọn ti fi ayọ̀ wá
S' ọ̀dọ̀ Rẹ, Olùgbàlà
Láti wá wolé fún 'Wọ...
T' ọ̀run àt' ayé ń jubà;
Bẹ́ẹ̀ ni k' á máa fi ayọ̀
Wá s' ibi ìtẹ́-àánú.
Bí wọn ti ta Ọ l' oore,
'Gbà t' Ó wà l' ọmọ-ọwọ́,
Bẹ́ẹ̀ ni k' á f' ayọ̀ mímọ́,
Láìní àbàwọ́n ẹ̀ṣẹ̀,
Mú iṣúra gbogbo wa
S' ọ̀dọ̀ Rẹ, Jésù Ọba.
Jésù mímọ́, pa wa mọ́,
L' ọ̀nà tóórò lójòojọ́
'Gbà t' ohun ayé bá pín,
Mú ọkàn wa dé ilú
Tí 'ràwọ̀ kìí ṣamọ̀nà,
T' ògo Rẹ kò farasín.