Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 91: Ẹ̀yin Áńgẹ́l' L' Ọ̀run Ògo

Angels from the Realms of Glory

Ẹ̀yin áńgẹ́l' l' ọ̀run ògo.
Tó yí gbogbo ayé ká;
Ẹ ti kọrin dídá ayé,
Ẹ sọ t' ibi Mẹ́sáyà;

Ẹ wá jọ sìn, Krístì Ọba títun
Ẹ wá jọ sìn, Sìn Krístì Ọba títun.

Ẹ̀yin Olùṣọ́ àgùtàn,
Tí ń ṣọ́ ẹran yín l' órù;
Emmánúẹ́lì wa ti dé,
Ìràwọ̀ ọmọ náà ń tàn;

Ẹ wá jọ sìn, Krístì Ọba títun
Ẹ wá jọ sìn, Sìn Krístì Ọba títun.

Ológbọ́n ẹ tú 'jú yín ká,
Ìràn dídàn ń tàn loke;
Ẹ wá ìfẹ́ orílẹ' èdè,
Ẹ ti rí ìràwọ̀ Rẹ.

Ẹ wá jọ sìn, Krístì Ọba títun
Ẹ wá jọ sìn, Sìn Krístì Ọba títun.

Oníìgbàgbọ́ tí ń tẹríba,
Ní 'bẹ̀rù àt' ìrètí,
L' òjìjì l' Olúwa ó dé,
Yóò yọ n' nú tẹ́ńpìlì Rẹ.

Ẹ wá jọ sìn, Krístì Ọba títun
Ẹ wá jọ sìn, Sìn Krístì Ọba títun.