Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 90: Ẹ Jí Kristẹ́n

Christians Awake!

Ẹ jí Kristẹ́n, kẹ́ ẹ kí oòrọ̀ ayọ̀,
Tí a bí Olùgbàlà aráyé;
Dìde, kẹ́ ẹ kọrin ìfẹ́ Ọlọ́run,
T' àwọn áńgẹ́lì ń kọ láti òkè,
Lát' ọ̀dọ̀ wọn n' ìyìn náà ti bẹ̀rẹ̀;
Ìyìn Ọm' Ọlọ́run t' á a bí s' ayé.

'Gbà náà l' á rán akédé Áńgẹ́lì,
T' ó sọ f' àwọn Olùṣ'àgùtàn pé,
"Mo mú 'hìn rere Olùgbàlà wa,
T' á bí fún yín àti gbogbo ayé;
Ọlọ́run mú 'lérí Rẹ ṣe lónì,
A bí Olùgbàlà Kríst' Olúwa"

Bí akédé Áńgẹ́l' náà ti sọ tán,
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun Ọ̀run sì dé;
Wọn ń kọrin ayọ̀ t' etí kò gbọ́ rí,
Ọ̀run sì hó fún 'yìn Ọlọ́run pé,
"Ọgọ́ ni f' Ọlọ́run l' òkè Ọ̀run,
Àlàáfíà àt' ìfẹ́ s' ènìyàn".

Ó yẹ k' àwa k' á máa rò l' ọkàn wa,
Ìfẹ́ ńlá t' Ọlọ́run ní s' aráyé
K' á sì rò t' Ọmọ náà t' á bí lóníì
T' Ó wá jìyà ọ̀rọ̀ àgbélébù,
Kí àwa sì tẹ̀lé ìlànà Rẹ,
Títí a ó fi dé 'búgbé l' òkè.