Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 89: Wá Ẹ̀yin Olóòótọ́

O Come All Ye Faithful

Wá ẹ̀yin olóòótọ́
L' ayọ̀ àt' ìṣẹ́gun
Wá k' á lọ, wá k' á lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù,
Wá k' á lọ wò Ó!
Ọba àwọn áńgẹ́lì.

Ẹ wá ká lọ jubà Rẹ
Ẹ wá ká lọ jubà Rẹ
Ẹ wá ká lọ jubà
Krístì Olúwa.

Áńgẹ́lì, ẹ kọrin,
Kọrin ìtọ́yẹ Rẹ;
Kí gbogbo ẹ̀dá ọ̀run sì gbérin:
Ọgọ́ f' Ọlọ́run
L' òkè ọ̀run lọ́hùn

Ẹ wá ká lọ jubà Rẹ
Ẹ wá ká lọ jubà Rẹ
Ẹ wá ká lọ jubà
Krístì Olúwa.

Nítòótọ́, a wolé,
F' Ọba t' á a bí lónì;
Jésù, Ìwọ ni àwa ń fi ògo fún:
'Wọ ọmọ Bàbá,
T' ó gbé ara wa wọ!

Ẹ wá ká lọ jubà Rẹ
Ẹ wá ká lọ jubà Rẹ
Ẹ wá ká lọ jubà
Krístì Olúwa.