Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 88: Gbà T' Àwọn Olùṣ'àgùtàn Ń Ṣọ́ Àgbò Wọn L' Órù

While Shepherds Watched Their Flocks

'Gbà t' àwọn olùṣ' àgùtàn
Ń ṣọ́ àgbò wọn l' órù,
Áńgẹ́l' Olúwa sọ kalẹ̀,
'Mọ́lẹ̀ sì yí wọn ká.

Áńgẹ́lì náà wí fún wọn pé,
'Ẹ má bẹ̀rù, n' torí
Mo mú 'hìn ayọ̀ tó yín wá,
Tí í ṣe t' èèyàn gbogbo.

'A bí Olùgbàlà fún yín
Ní ìlú Dáfídì,
Tí í ṣe Krístì Olúwa;
Èyí ni yóò j' àmì.

Ẹ ó rí ọmọ-ọwọ́ náà
Níbi tí a tẹ́ E sí,
Tí a fi ojà kan wè É
Ní ibùjẹ ẹran.

B' áńgẹ́lì náà ti sọ̀rọ̀ tán,
Ọgúnlọ́gọ̀ áńgẹ́l'
Ń kọrin 'yìn s' Ọlọ́run l' òkè,
Wọn kọrin báyìí pé:

Ọgọ́ f' Ọlọ́run l' ók' ọ̀run
Àlàáfíà f' ayé
K' ìfẹ́-inú-rere s' ènìyàn
Bẹ̀rẹ̀ lát' ìsisìyí.