Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 87: Ẹlẹ́wà Jùlọ N' N' Àwọn Ọmọ Oòrọ̀

Brightest and Best

Ẹlẹ́wà jùlọ n' n' àwọn ọmọ oòrọ̀!
Mọ́lẹ̀ s' oòkùn wa, k' ó ràn wá lọ́wọ́;
Ìràwọ̀ ìlà-oòrùn t' á á ṣe l' oṣó,
Sìn wa dé 'bìt' Olùgbàlà wa wà.

Ìrì tútù ń ṣe s' orí ibùsùn Rẹ;
Ó sùn jẹ̀jẹ̀ ní 'bùjẹ pẹ̀l' ẹran
Àwọn áńgẹ́lì sì yìn ín bí Ọ́ ti ń sùn,
Ẹlẹ́dàá, Ọba àt' Olùgbàlà.

A ó fún Un ní oore àtinúwá wa,
Oòrùn Édómù àt' oore ọ̀run,
Òkúta 'yebíye àt' iyùn òkun
Ọjìá lát' igbẹ́ àti wúrà

Ṣùgbọ́n àṣán l' á ó fún Un l' oore t' ó pọ̀,
Àṣán ni láti f' ẹ̀bùn w' ojú Rẹ;
Bí àwa kò bá f' ọkàn wa fún Un pẹ̀lú;
Ìsìn tòótọ́ ṣ' owón fún Ọlọ́run.

Ẹlẹ́wà jùlọ n' n' àwọn ọmọ oòrọ̀!
Mọ́lẹ̀ s' oòkùn wa, k' ó ràn wá lọ́wọ́
Ìràwọ̀ ìlà-oòrùn t' á ṣe l' ọ́ṣọ̀,
Sìn wa dé 'bìt' Olùgbàlà wa wà.