Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 84: Oore-Ọ̀fẹ́! Ohun Adùn Ni

Grace 'tis a Charming Sound

Oore ọ̀fẹ́! ohun,
Adùn ni l' etí wa,
Gbohùngbohùn rẹ̀ yóò gbà, ọ̀run kan,
Ayé yóò gbọ́ pẹ̀lú.

Oore ọ̀fẹ́ ṣàá
Ni 'gbẹ́kẹ̀lé mi
Jésù kú fún aráyé,
Ó kú fún mi pẹ̀lú.

Oore ọ̀fẹ́ l' ó kọ
Orúkọ mi l' ọ̀run
L' ó fi mí fún Od' àgùtàn.
T' ó gbà ìyà mi jẹ.

Oore ọ̀fẹ́ ṣàá
Ni 'gbẹ́kẹ̀lé mi
Jésù kú fún aráyé,
Ó kú fún mi pẹ̀lú.

Oore ọ̀fẹ́ tọ́ mi
Sọ̀nà àlàáfíà,
Ó ń tọ́jú mi lójòojúmọ́
Ní ìrìn ajò mi.

Oore ọ̀fẹ́ ṣàá
Ni 'gbẹ́kẹ̀lé mi
Jésù kú fún aráyé,
Ó kú fún mi pẹ̀lú.

Oore ọ̀fẹ́ tọ́ mi
Bí a ti ń gbàdúrà;
Ó ń pa mí mọ́ títí d' oní,
Kò sì jẹ́ kí n ṣako.

Oore ọ̀fẹ́ ṣàá
Ni 'gbẹ́kẹ̀lé mi
Jésù kú fún aráyé,
Ó kú fún mi pẹ̀lú.

Jẹ́ k' oore ọ̀fẹ́ yì
F' agbára f' ọkàn mi;
Kí n le fi gbogbo ipa mi
Àt' ọjọ́ mi fún Ọ.

Oore ọ̀fẹ́ ṣàá
Ni 'gbẹ́kẹ̀lé mi
Jésù kú fún aráyé,
Ó kú fún mi pẹ̀lú.