Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 82: Àánú Rẹ D' Ọ̀run Olúwa
Thy Mercy Lord Is In The Heavens
Àánú Rẹ d' ọ̀run Olúwa;
Òótọ́ Rẹ dé sánmọ̀;
Ododo Rẹ dàb' òkè nlá,
'Dájọ́ Rẹ b' ibú nlá.
Jésù, 'Wọ ń p' ohun gbogbo mọ́,
Oore Rẹ kún jọjọ!
N' torí náà abẹ́ iyẹ́ Rẹ
L' ọmọ Rẹ gbẹ́kẹ̀lé.
Ìbùkún láti ilé Rẹ
Ni yóò tẹ wọn lọ́run;
Ìwọ yóò mú wọn mu nínú
Omi odò 'fẹ́ Rẹ.
Nítorí pé Tìrẹ nìkan
Ni orísun ìyè;
Nínú ìmọ́lẹ̀ Rẹ pípé
L' àwa ó r' ọ̀go Rẹ.