Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 81: Ọlọ́run A Máa Ṣiṣẹ́ Rẹ L' Oníruúrú Ọ̀nà
God Moves In A Mysterious Way
Ọlọ́run a máa ṣiṣẹ́ Rẹ
L' oníruúrú ọ̀nà;
Ìpàṣẹ Rẹ ń bẹ nín' òkun
Ó gun igbì l' ẹ́ṣin.
Ẹ ṣe gírí, ẹ̀yin mímọ́
Ìṣòro t' ẹ ń wò ni
Kún f' àánú tí yóò sọ kalẹ̀
B' ìbùkún sorí yín.
Má f' ọ̀pẹ́ dá Jésù lẹ́jọ́
Ṣàá gbẹ́kẹ̀l' oore Rẹ
Nígbà t' ẹ̀yin ń rò p' Ó bínú
Ẹ̀rín l' Ó ń rín sí i yín.
Àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ fẹ́rẹ̀ ṣe,
Yóò túbọ̀ yé wa sí;
Bí ó tilẹ̀ burú l' oní
Yóò padà dùn lọ́la.
Àìgbàgbọ́ ń mú ni ṣìnà
Ó sọ 'ṣẹ́ Rẹ d' àṣán
Ọlọ́run tikára Rẹ ni
Yóò m' ọ̀nà Rẹ yé ni.