Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 80: Ọlọ́run Bẹ́tẹ́lì

O God of Bethel

Ọlọ́run Bẹ́tẹ́lì, Ẹni tí
Ó ń bò àwọn Tirẹ̀;
Ẹni t' ó mú bàbá wa là
Ọjọ́ ayé wọn jà.

A mú ẹ̀jẹ̀, àt' ẹ̀bẹ̀ wa
Wá íwájú 'tẹ́ Rẹ,
Ọlọ́run àwọn bàbá wa,
Máa jẹ́ Ọlọ́run wa.

Nínú ìdààmú ayé yìí,
Máa tọ́jú 'ṣiṣẹ́ wa;
Fún wa ní oúnjẹ óòjọ wa,
Àt' aṣọ t' ó yẹ wa.

Nà ojìjì 'yẹ́ Rẹ bò wá,
Títí ajò wa ó pín,
Àti ní 'búgbé Bàbá wa,
Ọkàn wa ó sìmí.

Irú ìbùkún bí èyí,
L' á ń bèèrè lọ́wọ́ Rẹ;
Ìwọ ó jẹ́ Ọlọ́run wa
Àt' ìpín wa láéláé.