Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 8: N Ó Kọrin Ìyìn Àt' Ọpẹ́
Now in a Song of Grateful Praise
N ó kọrin ìyìn àt' ọpẹ́,
L' ohùn mi s' Olúwa ọ̀wọ́n;
N ó pẹ̀l' àwọn mímọ́ ròhìn,
Jésù mi ṣe 'hun gbogbo rẹ̀.
A ni ìró yìí y' ó dùn jù bẹ́ẹ̀ lọ,
'Ró yìí yóò dùn, 'ró yìí yóò dùn,
Kíkankíkan ni 'ró yóò dùn,
Jésù mi ṣe 'hun gbogbo rẹ̀.
B' olùdánwò tafà iná,
Lọ́pọ̀lọ́pọ̀ sí mi l' àyà;
Èyí ni n ó fi ṣepa rẹ̀,
Jésù mi ṣe 'hun gbogbo rẹ̀.
A ni ìró yìí y' ó dùn jù bẹ́ẹ̀ lọ,
'Ró yìí yóò dùn, 'ró yìí yóò dùn,
Kíkankíkan ni 'ró yóò dùn,
Jésù mi ṣe 'hun gbogbo rẹ̀.
Gbà m' bá yọ s' ilú dídan náà,
Tí mo gbà 'bùgbé mi l' òkè
Yúngbà yúngbà n' ìró yóò dùn,
Jésù mi ṣe 'hun gbogbo rẹ̀.
A ni ìró yìí y' ó dùn jù bẹ́ẹ̀ lọ,
'Ró yìí yóò dùn, 'ró yìí yóò dùn,
Kíkankíkan ni 'ró yóò dùn,
Jésù mi ṣe 'hun gbogbo rẹ̀.