Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 76: Gbogbo Ohun T' Ó Dára
All Things Bright and Beautiful
Gbogbo ohun t' ó dára,
Gbogb' ẹ̀dá ayé yìí,
Àti gbogb' ohun 'yànu,
Ọlọ́run l' ó dá wọn.
Àwọn 'tànná kékeèké
Àti àwọn ẹyẹ
Ó ṣe àwọ̀ wọn dídàn,
Ó ṣe iyẹ́ wọn rẹ
Gbogbo ohun t' ó dára,
Gbogb' ẹ̀dá ayé yìí,
Àti gbogb' ohun 'yànu,
Ọlọ́run l' ó dá wọn.
Àwọn òkè tí ó ga,
Àwọn odò ṣíṣàn;
Àṣálẹ́ àt' òwúrọ̀,
Yóò m' àwọ̀sánmà dàn
Gbogbo ohun t' ó dára,
Gbogb' ẹ̀dá ayé yìí,
Àti gbogb' ohun 'yànu,
Ọlọ́run l' ó dá wọn.
Afẹ́fẹ́ ìgb' òtútù,
Oòrùn ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn,
Èso pípọ̀n nín' ọgbà,
Òun l' ó dá gbogbo wọn
Gbogbo ohun t' ó dára,
Gbogb' ẹ̀dá ayé yìí,
Àti gbogb' ohun 'yànu,
Ọlọ́run l' ó dá wọn.
Ó f' ojú 'ríran fún wa,
Àt' ẹnu láti sọ
B' Olódùmarè ti ó
Dá wọn tí tóbi tó