Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 75: Àwọ̀sánmà L' Òkè Gíga
The Spacious Firmament
Àwọ̀sánmà l' òkè gíga,
Pẹ̀lú gbogb' ẹwà dídàn rẹ̀,
Bí wọn ti ń dàn nín' ẹwà wọn,
Ni wọn ń fi ìyìn f' Ẹlẹ́dà,
Iṣẹ́ oòrùn lójojúmọ́
Fi agbára Ẹlẹ́dàá hàn
Ó tàn ròyìn Rẹ k' agbáyé
Iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run wa.
Nígbàt' ilẹ̀ bá sì sú tan,
T' oṣùpá sì yọ n' n' ọlá rẹ̀;
Òun yóò sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ
Ìtàn ìyànu dídá rẹ̀:
Iná t' ó ń jó n' n' àwọn
'ràwọ̀ t' ìmọ́lẹ̀ ayé yòkù
Ni ń jẹ́rí agbára Rẹ ká
Gbogbo agbà ń lá-ayé.
Bí ẹ̀dá kò ní ìmọ́lẹ̀
T' á sì ń rìn nínú òkùnkùn
Bí a kò gbọ́ ohùn tàbí
Ìró ní ayé dídàn yìí
Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni f' Ọlọ́run,
Ẹni t' ó f' ọgbọ́n dá ayé;
A ó máa kọrin ìyìn sí I pé,
"Ọwọ́ Ọlọ́run l' ó dá wa".