Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 74: T' Ọlọ́run L' Ayé Yìí
This Is My Father's World
T' Ọlọ́run l' ayé yìí,
Etí mi kún f' orin;
Tí àwọn ẹ̀dá gbogbo ń kọ,
Orin ìyìn l' òkè.
T' Ọlọ́run l' ayé yìí,
Ó sì hàn sí mi bẹ́ẹ̀
Tór' òun l' ó dá 'lẹ̀ àt' òkun
Àti àwọ̀sánmà.
T' Ọlọ́run l' ayé yìí,
Ẹyẹ ń kọrin ìyìn
Ìmọ́lẹ̀ ògo òwúrọ̀,
Ń kọrin 'yìn Ẹlẹ́dà
T' Ọlọ́run l' ayé yìí,
Iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ ni,
Gbogb' ohun t' ó kún fún ẹwà,
Ń jẹ́r' iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ.
T' Ọlọ́run l' ayé yìí,
Má jẹ́ kí n gbàgbé láé
Pé b' ibi ti pọ̀ tó ṣìbẹ̀
Ọlọ́run l' Ọb' ayé,
T' Ọlọ́run l' ayé yìí,
N kò ní b' ọkàn jẹ,
Jésù j' Ọba! jẹ́ k' ayé yọ̀,
Kí 'yìn yí 'tẹ́ Rẹ ká.