Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 73: Gbọ́! Ọkàn Mi Bí Ẹ̀dá

Hark My Soul How Everything

Gbọ́! ọkàn mi bí ẹ̀dá
Tí ń sìn Ọba olóore;
Wọn ń kọrin, wọn sì ń tùúbá
F' Ọlọ́run Ẹlẹ́dá wọn.

Ẹ̀dá pẹ̀l' ohùn gòòrò
Ń kọrin ìyìn s' Ọba wọn,
Igbó àt' odàn ń kọrin,
Ìyìn sí Ẹlẹ́dá wọn.

Nínú ohùn jẹ̀jẹ̀ wọn,
Odò ṣíṣàn ń kọrin 'yìn
Ṣíṣàn wọn t' órù t' ọ̀sán
Ń kọrin jubà Ọba wọn.

Gbogbo odòdó tútù,
L' ó ń kọrin n' nú dákẹ́ jẹ́ẹ́
Bí Oòrùn bá búkún wọn,
Wọn á yọ nín' ẹwà wọn.

Jí n' nú 'tìjúù 'w' ọkàn mi,
Jí sí yìn Ẹlẹ́dàá rẹ
Kọ lọ́dọ̀ ẹ̀dá gbogbo,
Bí a ti ń yìn Ẹlẹ́dàá.