Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 71: 'Wọ Ìmọ́lẹ̀ Ayérayé

Eternal Light! Eternal Light!

'Wọ Ìmọ́lẹ̀ ayérayé
Ọkàn náà tí mọ́ tó,
T' ó le dúró níwájú Rẹ,
Láì bẹ̀rù ṣùgbọ́n pẹ̀l' ayọ̀
K' ó máa wò ojú Rẹ.

Àwọn ẹ̀mí t' ó yí Ọ ká
Le wò ìmọ́lẹ̀ náà;
Àwọn nìkan ni ó le wò ó,
Nítorí wí pé wọn kò mọ̀
Ayé ẹ̀ṣẹ̀ b' èyí.

A! báwo l' ẹ̀mí ènìyàn
Ẹlẹ́ṣẹ̀ lásán yìí,
Yóò ṣe yojú s' Ẹni Mímọ́.
Àti ní àìnílárí mi
Wò 'mọ́lẹ̀ dídàn Rẹ?

Ọ̀nà wà t' á le bá gòkè
Sí ibi mímọ́ náà:
Ẹ̀mí Mímọ́ lo ń ṣe 'ràńwọ́
Nípa oore àt' ẹ̀tùtù,
Alágbàwí sì ń bẹ̀.

Àwọn yìí pèsè wá sílẹ̀
Fún ibi mímọ́ náà;
Kí àwọn ọmọ òkùnkùn
Lè gbé 'nú 'mọ́lẹ̀ aìlópin,
Nípa ìfẹ́ Jésù.