Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 7: Ọlọ́run Àìkú, Ọlọ́gbọ́n Jùlọ
Immortal, Invisible, God only Wise
Ọlọ́run àìkú, Ọlọ́gbọ́n jùlọ,
Ẹn' ayé kò lè rí,
Ó ń gbé 'nú 'mọ́lẹ̀,
Olùbùkún jùlọ, Ọba 'yérayé,
Ògo f' orúkọ Rẹ, Bàbá Aṣẹ́gun.
Agbára Rẹ nìkan l' ó lè gbé wa rò,
Ìwọ t' Ó ń ṣiṣẹ́ Rẹ nínú 'dákẹ́jẹ́
Òdodo Rẹ ga jù òkè gíga lọ,
Àwọ̀sánmà Rẹ jẹ́, Orísun ìfẹ́.
Gbogbo ẹ̀dá n' Ìwọ fún l' ẹ̀mí ìyè;
Ṣùgbọ́n ìyè Tìrẹ, l' àpéré pípé
A ń dàgbà a sì ń kú, gẹ́gẹ́ b' ewéko,
Ṣùgbọ́n Ìwọ nìkan ló wà títí láé.
Bàbá Alágbára t' Ó ń gbé 'nú 'mọ́lẹ̀,
Àwọn angẹ́lì ń yìn Ọ, wọ́n ń bò 'jú wọn;
Gbogbo ìyìn yẹ Ọ, jọ̀wọ́ jẹ́ k' á mọ̀
Pé ìmọ́lẹ̀ ológo ló bò 'jú Rẹ.