Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 69: Ṣàá Tó O Wò, Rere L' Ọlọ́run
O Taste and See
Ṣàá tó O wò, rere l' Ọlọ́run;
'Bùkún f' ẹni bá mọ̀ Ọ́
Bẹ̀rù Rẹ, n' torí kò s' àìní
F' ẹni t' ó bẹ̀rù Rẹ.
Ebi lè p' ọmọ kìnìún,
Wọ́n sì le ṣàì l' oúnjẹ
Ṣùgbọ́n àwọn t' ó w' Olúwa
Yóò ní ohun rere.
Ẹ wá ná, ẹ̀yin ọmọ mi,
Ẹ fi etí sí mi;
Èm' ó kọ́ yín láti m' òye
B' ẹ ṣe le bẹ̀rù Rẹ.
Ọkùnrin wo l' ó ń fẹ́ ìyè
Àti ọjọ́ púpọ̀?
M' ẹ̀tàn kúrò ní ẹnu rẹ,
Má ṣe sọ̀rọ̀ ibi.
Kọ ibi, sì máa ṣe rere.
Máa wá àlàáfíà
Ọlọ́run ń sọ olódodo
Ó sì ń gbọ́ igbe wọn.