Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 68: Ọlọ́run Mi Ti Tóbi Tó

How Great Thou Art

Ọlọ́run mi, 'gbà mo rò 'ṣe ọwọ́ Rẹ,
Ó di ohun ìran 'yanu fún mi;
Mo rí 'ràwọ̀, mo gbọ́ ọ̀run ń
sàn àárá,
Wọn ń f' agbára Rẹ l' orí ayé hàn.

Bẹ́ẹ̀ l' ọkàn mi kọrin sí
Ọba mi, Ọlọ́run mi ti tóbi tó!
Bẹ́ẹ̀ l' ọkàn mi kọrin sí
Ọba mi, Ọlọ́run mi ti tóbi tó!

'Gbà mo ṣìnà wo igbó àt' ijù lọ,
Tí mo gb' ohùn àwọn ẹyẹ tí
ń kọrin;
Gbà mo wò 'lẹ̀ lát' or'
òkè gíga wá,
Tí mo gb' orin àwọn odò t'
ó ń sàn.

Bẹ́ẹ̀ l' ọkàn mi kọrin sí
Ọba mi, Ọlọ́run mi ti tóbi tó!
Bẹ́ẹ̀ l' ọkàn mi kọrin sí
Ọba mi, Ọlọ́run mi ti tóbi tó!

'Gbà mo rò t' ọm' Ọlọ́run
t' á fi rúbọ,
Ẹ̀rù bà mí, ó kún mi lójú pé
Jésù rù ẹ̀ṣẹ̀ mi l' or' àgbélébù;
Ó kú kí Òun le wẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mi nù.

Bẹ́ẹ̀ l' ọkàn mi kọrin sí
Ọba mi, Ọlọ́run mi ti tóbi tó!
Bẹ́ẹ̀ l' ọkàn mi kọrin sí
Ọba mi, Ọlọ́run mi ti tóbi tó!

'Gbà Krístì bá dé
pẹ̀l' àríwó ayọ̀,
Yóò ti dùn tó bí n' bá le bá rẹ 'lé
'Gbà náà n ó sìmí
ní 'rẹ̀lè àt' ìfẹ́,
N' ó ké pé: "Títóbi l' Ọlọ́run mi".

Bẹ́ẹ̀ l' ọkàn mi kọrin sí
Ọba mi, Ọlọ́run mi ti tóbi tó!
Bẹ́ẹ̀ l' ọkàn mi kọrin sí
Ọba mi, Ọlọ́run mi ti tóbi tó!