Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 67: N' Ó Kọrin Ipa Ọlọ́run
I Sing the Mighty Power
N' ó kọrin ipa Ọlọ́run,
T' Ó mú k' òkè dìde,
T' Ó dá òkun tí ń sàn yíká,
T' Ó dá sánmà dídàn;
N' ó kọrin ọgbọ́n t' ó jẹ́ kí,
Oòrùn jobà ọ̀sán;
Oṣùpá n' ràn ní àṣẹ Rẹ,
Àwọn 'ràwọ̀ sì n' yọ.
N' ó kọrin oore Olúwa,
T' ó f' oúnjẹ kún ayé;
Ó dá ayé pẹ̀l' ọ̀rọ̀ Rẹ,
Ó sọ pé wọn dára!
Olúwa f' agbára Rẹ hàn,
Níbi gbogbo t' á n' rí,
Ní orí ilẹ̀ tí mo n' rìn,
Àti l' ojú sánmà.
Kò sí igi tàb' odòdó,
Tí kò f' ọ̀go Rẹ hàn;
Ìkùúkùú ń yọ, ìjì sì ń fẹ́,
Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Rẹ,
Àwọn ẹ̀dá t' Ó fún l' ẹ̀mí,
Wà lábẹ́ 'tọ́jú Rẹ;
Kò síbi tí a le sálọ,
T' Ọlọ́run kò sí ń bẹ̀.