Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 62: Ẹ Wolé F' Ọba, Ológo Jùlọ

O Worship The King

Ẹ wole f' Ọba, Ológo jùlọ,
Ẹ kọrin ipa àti ìfẹ́ Rẹ;
Aláàbò wa ni àt' Ẹni Ìgbà ni,
Ó ń gbé inú ọ̀gọ,
eléru ń 'yìn.

Ẹ sọ t' ipa Rẹ, ẹ sọ t' oore Rẹ
'Mọ́lẹ̀ l' aṣọ Rẹ, gòbì Rẹ̀ ọ̀run,
Bí àárá tí ń sán ni kẹ̀kẹ́ 'bínú Rẹ;
Ipa ọ̀nà Rẹ ni a kò sí le mọ̀.

Ìtọ́jú Rẹ wà lára gbogbo wọn,
Nínú afẹ́fẹ́, nínú ìmọ́lẹ̀;
Ìtọ́jú Rẹ wà nínú odò tí ń ṣàn,
Ó sì wà nínú ìrì àti òjò.

Àwa erùpẹ̀, àw' aláìlera,
'Wọ l' à gbẹ́kẹ̀lé, 'Wọ kì yóò bàkú;
Àánú Rẹ ni ronú, ó dúró láéláé,
Ẹlẹ́dàá, Aláàbò, Olùgbàlà wa.