Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 619: Ṣ' Ọmọ Ọlọ́run Ni Wọ́n Ń Pè Wá?
Are We Called the Children of God?
Ṣ' ọmọ Ọlọ́run ni wọ́n pè wá,
Tí 'nú wa ń dùn
Ṣ' ọmọ Ọlọ́run ni wọ́n ń pè wá o,
Tí 'nú wa ń dùn,
Tí ọkàn wa ń yọ ṣẹ̀ṣẹ̀
Ṣùgbọ́n ìwà wa, hà jọ t' Ẹlẹ́dàá bí?
Ṣ' ọmọ Bàbá o, Ọ̀rẹ́ ṣ' ọmọ Bàbá.
Nítorí pé ẹni bí ni Òun l' a á jọ.