Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 611: Ọlọ́run Fọ̀hùn L' Átetekọṣe
God Declared It From The Beginning
Ọlọ́run fọ̀hùn, l' átetekọṣe,
Ní ọjọ́ mẹ́fà, l' ó dá ọ̀run oùn ayé o.
Àwí-má-yẹ̀hùn, A-sọ-má-taṣe o,
A-sọ̀rọ̀-máyẹ̀, Ọlọ́run mi, mo bẹ̀rù Rẹ.
Ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ l' ẹ̀tí okun l' Ọlọ́run,
Ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ f' Ọba Fáráò l' ẹ̀tí okun,
Ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ f' Ọba Fáráò l' ẹ̀tí okun pupa;
Yẹ Jèhófà Bàbá l' Ọ̀run, mo bẹ̀rù Rẹ.
Ọlọ́run fọ̀hùn s' àwọn Ọlótẹ̀,
Korah, Datani àti gbogb' àwọn ẹgbẹ́ wọn,
Ilẹ̀ yanú rẹ̀, Ó sì gbé wọn mì;
Àwí-má-yẹ̀hùn, Ọlọ́run mi, mo bẹ̀rù Rẹ.
Ọba fọ̀hùn Rẹ, fọ̀hùn 'bùkún Rẹ
Jẹ́ kí gbogbo wa l' ayọ̀ nínú oore Rẹ
Jẹ́ k' a j' olóòótọ́, sí gbogb' àṣẹ Rẹ
Àwí-má-yẹ̀hùn, Ọlọ́run wa, a bẹ̀rù Rẹ