Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 6: Ọb' Àt' Ẹlẹ́dàá Mi
My Maker and My King
Ọb' àt' Ẹlẹ́dàá mi
Ọpẹ́ f' ohun gbogbo;
Ìwọ ni orísun 'bùkún
Àt' ìrànlọ́wọ́ mi.
Ìwọ ni orísun 'bùkún
Àt' ìrànlọ́wọ́ mi.
Èm' ẹ̀dá ọwọ́ Rẹ,
'Wọ mú mi wà láàyè
Jésù, ìbùkún tó O fún mi
Pọ̀ jù ọpẹ́ mi lọ
Jésù, ìbùkún tó O fún mi
Pọ̀ jù ọpẹ́ mi lọ.
Ohun gbogbo n' Tìrẹ,
Kíni mo rí fúnni?
Ìfẹ́ Rẹ béèr' ọkàn 'moore
A! ọrẹ mi kéré.
Ìfẹ́ Rẹ béèr' ọkàn 'moore
A! ọrẹ mi kéré.
A, jẹ k' or'-ọ̀fẹ́ Rẹ
F' ọkàn mi lágbára;
Jẹ́ kí ń máa lo ọj' ayé mi
Àt' ìfẹ́ mi fún Ọ.
Jẹ́ kí ń máa lo ọj' ayé mi
Àt' ìfẹ́ mi fún Ọ.