Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 59: Ayérayé Ni 'Fẹ́ Bàbá
O Love of God
Ayérayé ni 'fẹ́ Bàbá,
Aìlópin ni, ó wà láéláé
Kò le yé ni, a kì í 'rí i rà,
Ó tayọ irọ́ àt' ọgbọ́n.
Ìfẹ́ Bàbá ti jìnlẹ̀ tó,
Àwọ̀sánmà ń sọ nípa rẹ̀,
Ilẹ̀ ayé sì ń fi Ọ́ hàn
Òkun, àt' odò ń kígbe Rẹ.
A mọ̀ Ọ́ n' nú Ẹni t' Ó wá,
Tí Ó sì gbà ìyà wa jẹ;
Tí Bàbá rán lát' òkè wá,
Láti kú f' àwa ẹ̀dá Rẹ.
A mọ̀ nípa agbára Rẹ
Láti gbà ni lọ́wọ́ ikú;
Ṣìbẹ̀ ìmọ̀ àjíǹde Rẹ
Fi ẹ̀kún agbára Rẹ hàn.
Ìfẹ́ Ọlọ́run, Aàbò wa
Láàrín gbogbo ewu ayé,
Nínú Rẹ ni àwa sìmí:
Máa sọ wa, k' Ó sì búkún wa.