Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 580: Gbà T' Òkùnkùn Bá Rékọjá

When Darkness Passes Over

Gbà t' òkùnkùn bá rékọjá,
T' ọjọ́ ayọ̀ bá sì dé tán;
Tí 'tànsán oòrùn fara hàn,
Lórí àwọn ìṣàn omi;
T' a ń retí 'lérí Bàbá wa,
Ní dídàn òṣùmàrè,
A ó mọ 'ra wa, a ó rí 'ra wa
Gbà t' òkùnkùn bá kọjá
A ó mọ 'ra wa, a ó rí 'ra wa
Gbà t' òkùnkùn bá kọjá

A ó mọ yín arákùnrin
A ó mọ yín arábìnrin
A ó rí yín arákùnrin
A ó rí yín arábìnrin
L' òwúrọ̀ ọjọ́ dídàn náà
Ọjọ́ t' ó l' ògó jùlọ
A ó rí 'ra wa, a ó mọ 'ra wa
Gbà t' òkùnkùn bá kọjá.