Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 58: Ọlọ́run 'Yànú Ọgọ́ Rẹ
Stand Still and See
Ọlọ́run 'yànú! ògo Rẹ
Ń hàn nínú gbogbo iṣẹ́ Rẹ;
Ṣùgbọ́n Oòr'-ọ̀fẹ́ 'dàríjì
Jẹ́ ohun ìyànu jùlọ;
Ọlọ́run, tani dàbí Rẹ?
Oore tani pọ̀ bí Tìrẹ?
N' ìyànu àt' ayọ̀ l' à gbà
Ìdàríjì Ọlọ́run wa;
'Dàríjì f' ẹ̀ṣẹ̀ t' ó tóbi
T' ẹ̀jẹ̀ Jésù ṣe tútù fún;
Ọlọ́run, tani dàbí Rẹ?
Oore tani pọ̀ bí Tìrẹ?
Jọ̀ọ́, jẹ́ k' oore-ọ̀fẹ́ Rẹ yìí,
Ìfẹ́ ìyànu nlá Rẹ yìí,
Fi ìyìn kún gbogbo ayé,
Bí t' ẹgbẹ́ akọrin l' òkè!
Ọlọ́run, tani dàbí Rẹ?
Oore tani pọ̀ bí Tìrẹ?