Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 571: Bí Mo Ti Rí

Whatever I Was Or Will Ever Be

Bí mo ti rí tí n ó sì jẹ́,
Ọmọ Ọlọ́run l' ó ń tọ́ mi,
Ó ti rà mi Tirẹ ni mi
Nípa ìfẹ́ t' èmi ni Òun.

Àánú Rẹ̀ rà mi, ìfẹ́ Rẹ̀ gbà mi,
Oor' ọ̀fẹ́ Rẹ̀ fún mi n' gbàgbọ́;
Nínú ìgbàgbọ́ mo l' àlááfíà,
Ní inú rẹ̀ ni èmi ń gbé.

Ọ̀rọ̀ àgbélébùú Rẹ̀ tó
Láti mú gbogb' ẹ̀ṣẹ̀ mi lọ;
Bíbàgbé àt' agbára Rẹ̀
L' ó mú gbogbo èrò mi tó

Àánú Rẹ̀ rà mi, ìfẹ́ Rẹ̀ gbà mi,
Oor' ọ̀fẹ́ Rẹ̀ fún mi n' gbàgbọ́;
Nínú ìgbàgbọ́ mo l' àlááfíà,
Ní inú rẹ̀ ni èmi ń gbé.

Àyọrísí gbogbo 'yà Rẹ̀
Ni a dàrí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì;
Ikú Rẹ̀ Krístì l' ó fún mi
Ní ìyè tí kò ní pẹ́kun

Àánú Rẹ̀ rà mi, ìfẹ́ Rẹ̀ gbà mi,
Oor' ọ̀fẹ́ Rẹ̀ fún mi n' gbàgbọ́;
Nínú ìgbàgbọ́ mo l' àlááfíà,
Ní inú rẹ̀ ni èmi ń gbé.