Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 57: Mímọ́, Mímọ́, Mímọ́! Olódùmarè

Holy, Holy, Holy! Lord God Almighty

Mímọ́, mímọ́, mímọ́!
Olódùmarè!
Ní kùtùkùtù n' Ìwọ ó gbọ́ orin wa;
Mímọ́, mímọ́, mímọ́,
Oníyọ̀nú jùlọ!
Ológo mẹ́ta; láé Olùbùkún!

Mímọ́, mímọ́, mímọ́!
Àwọn ángẹ́lì n yìn ín,
Ńwọ́n ń fi adé wúrà
wọn lélé y' ìtẹ́ ká:
Kérúbù, Séráfù ń
Wolé ní 'wájú Rẹ,
Wò t' Ó ti wà, tó Ó sì wà títí láé.

Mímọ́, mímọ́, mímọ́!
b' òkùnkùn pa Ọ mọ́,
Bí ojú ẹlẹ́ṣẹ̀ kò le rí ọ́go Rẹ.
Ìwọ nìkan l' Ó mọ̀, kò tún sí ẹlòmíì,
Pípé n' nú agbára àti n' ìfẹ́

Mímọ́, mímọ́, mímọ́!
Olódùmarè!
Gbogbo iṣẹ́ Rẹ n' ilẹ̀ l' òkè l' ó ń yìn Ọ;
Mímọ́, mímọ́, mímọ́,
Oníyọ̀nú jùlọ!
Ológo mẹ́ta, láé Olùbùkún!