Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 566: Àgọ́ Rẹ̀ Wọ̀nní Ti Ní Ẹwà Tó Olúwa

How Lovely Are Your Tabernacles

Àgọ́ Rẹ̀ wọ̀nní ti ní
Ẹwà tó, Olúwa
Ẹwà tó, Olúwa
Ọkàn mi fà s' ilé ọ̀run
Ọkàn mi fà s' ilé ọ̀run
'Tórí àwọn ẹyẹ ọ̀run n' ilé,
Wọ́n n' ilé l' orí 'gi
Àlàpàndẹ̀dẹ́ wọn ní ìtẹ́ o, ìtẹ́ ògo.
Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ẹgbẹ́,
Ẹgbẹ́ oníìgbàgbọ́
Àwa n' ilé, ilé ayọ̀ l' ọ̀dọ̀ Rẹ̀
Olúwa Ìbùkún o,
Alelúyà, Ìbùkún o,
Alelúyà, Ìbùkún o.