Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 565: Adé Kan Ń Bẹ Fún Kristẹni
There Is A Crown For The Christian
Adé kan ń bẹ fún Kristẹni
Ní òkè ọ̀run;
Kò dàbí adé ayé O,
T' ó lè bajẹ́ bó pẹ́.
Ó dára, ó dára láti jẹ́ ti Krístì,
Ìbùkún ń bẹ fún wa lókè
Lọ́dọ̀ Olórí wa.
Ilé kan ń bẹ fún Kristẹni
Ní òkè ọ̀run;
Kò dàbí ilé ayé o,
T' ó lè bajẹ́ b' ó pẹ́.
Ó dára, ó dára láti jẹ́ ti Krístì,
Ìbùkún ń bẹ fún wa lókè
Lọ́dọ̀ Olórí wa.
'Simi kan ń bẹ fún Kristẹni
Ní òkè ọ̀run;
Kò dàbí simi ayé o,
T' ó lè bajẹ́ b' ó pẹ́.
Ó dára, ó dára láti jẹ́ ti Krístì,
Ìbùkún ń bẹ fún wa lókè
Lọ́dọ̀ Olórí wa.