Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 524: F' Epo S' Àtùpà Mi

Give Me Oil In My Lamp

F' epo s' àtùpà mi kí n lè máa jó
F' epo s' àtùpà mi Jésù;
F' epo s' àtùpà mi kí n lè máa jó
Kí n lè máa tàn títí d' ọjọ́ náà

Kọ Hòsánà, kọ Hòsánà,
Kọ Hòsánà, s' Ọba wọn ọba;
Kọ Hòsánà, kọ Hòsánà,
Kọ Hòsánà, s' Ọba wa.

Ṣe mi l' apẹja àwọn ènìyàn
Ṣe mi l' apẹja 'wọn ènìyàn
Ṣe mi l' apẹja àwọn ènìyàn.
Kí n kún fún iṣẹ́ dé bíbọ̀ Rẹ̀.

Kọ Hòsánà, kọ Hòsánà,
Kọ Hòsánà, s' Ọba wọn ọba;
Kọ Hòsánà, kọ Hòsánà,
Kọ Hòsánà, s' Ọba wa.