Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 510: Jésù Ìjì Líle Ti Ń Jà

Master The Tempest Is Raging

Jésù ìjì líle ti ń jà
Ẹfúùfù ńlá sì ti ń fẹ́,
Òkùnkùn ńlá sì sú bò ilẹ̀,
Ìrànwọ́ jìnnà sí wa.
Ikú wa kò jẹ́ ǹkan fún Ọ
Ó ṣe lè wá máa sùn
Gbà tí gbogbo àkókò kún f' ẹ̀rù
Tí 'bojì wa wà n' nú 'bú?

Ẹfúùfù àt' ìjì yóò gb' àṣẹ Mi
Dúró jẹ̀ẹ́,
Kíbàá sì jẹ́ ìrúmi òkun,
Èṣù tàbí ohun-kohun t' ó lè jẹ́
Kò s' ìgbì t' ó lè gb' okò níbi tí
Ẹni t' ó ní ayé àt' Ọ̀run wà
Gbogbo wọn yóò gbọ́ àṣẹ T' Èmi
Dúró jẹ̀ẹ́! dúró jẹ̀ẹ́
Gbogbo wọn yóò gbọ́ Àṣẹ T' Èmi
Dúró jẹ̀ẹ́!

Olúwa, t' ẹ̀dùn, t' ẹ̀dùn ọkàn
Ni mo tẹrí bá lónìí
Ìbànújẹ́ ti gbà ọkàn mi,
A! yára wá gbà mi là!
Ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ oun 'bànújẹ́,
Wò ọkàn mi léwu;
Mo ń ṣègbé, mo ń ṣègbé lọ ní yìí,
Yára láti gbà mi là.

Ẹfúùfù àt' ìjì yóò gb' àṣẹ Mi
Dúró jẹ̀ẹ́,
Kíbàá sì jẹ́ ìrúmi òkun,
Èṣù tàbí ohun-kohun t' ó lè jẹ́
Kò s' ìgbì t' ó lè gb' okò níbi tí
Ẹni t' ó ní ayé àt' Ọ̀run wà
Gbogbo wọn yóò gbọ́ àṣẹ T' Èmi
Dúró jẹ̀ẹ́! dúró jẹ̀ẹ́
Gbogbo wọn yóò gbọ́ Àṣẹ T' Èmi
Dúró jẹ̀ẹ́!

Jésù ìdààmú rẹ kọjá,
Ewu gbogbo ti d' òpin;
Òjìjì àlááfíà bò 'lẹ̀,
Ayọ̀ sì kún ọkàn mi,
Dúró ti mi Olùgbàlà,
Má fi mi sílẹ̀ mọ́,
Pẹ̀lú ayọ̀ ni n ó gòkè odò,
N' ó simi níbi ayọ̀.

Ẹfúùfù àt' ìjì yóò gb' àṣẹ Mi
Dúró jẹ̀ẹ́,
Kíbàá sì jẹ́ ìrúmi òkun,
Èṣù tàbí ohun-kohun t' ó lè jẹ́
Kò s' ìgbì t' ó lè gb' okò níbi tí
Ẹni t' ó ní ayé àt' Ọ̀run wà
Gbogbo wọn yóò gbọ́ àṣẹ T' Èmi
Dúró jẹ̀ẹ́! dúró jẹ̀ẹ́
Gbogbo wọn yóò gbọ́ Àṣẹ T' Èmi
Dúró jẹ̀ẹ́!