Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 509: Kò S' Ọ̀rẹ́ Bí Jésù Onírẹ̀lè

There's Not A Friend Like The Lowly Jesus

Kò s' ọ̀rẹ́ bí Jésù Onírẹ̀lè,
Kò s' ọ̀rẹ́, kò s' ọ̀rẹ́;
Kò s' ẹni t' ó lè wò ọkàn wa sàn
Kò s' ẹni, kò s' ẹni.

Jésù mọ̀ gbogbo ìdánwò wa,
Yóò tọ́jú wa títí d' òpin;
Kò s' ọ̀rẹ́ bí Jésù Onírẹ̀lè,
Kò s' ọ̀rẹ́, kò s' ọ̀rẹ́;

Kò s' ọ̀rẹ́ t' ó jẹ́ mímọ́ bí Jésù,
Kò s' ọ̀rẹ́, kò s' ọ̀rẹ́;
Kò s' ẹni t' ó ní 'nú tutù bí Rẹ̀
Kò s' ẹni, kò s' ẹni.

Jésù mọ̀ gbogbo ìdánwò wa,
Yóò tọ́jú wa títí d' òpin;
Kò s' ọ̀rẹ́ bí Jésù Onírẹ̀lè,
Kò s' ọ̀rẹ́, kò s' ọ̀rẹ́;

Kò s' ìgbà kan t' Òun kò sí lọ́dọ̀ wa,
Kò s' ìgbà, kò s' ìgbà;
Kò s' ìgbà tí 'fẹ́ Rẹ̀ kò tù wa n' nú
Kò s' ìgbà, kò s' ìgbà.

Jésù mọ̀ gbogbo ìdánwò wa,
Yóò tọ́jú wa títí d' òpin;
Kò s' ọ̀rẹ́ bí Jésù Onírẹ̀lè,
Kò s' ọ̀rẹ́, kò s' ọ̀rẹ́;

Ẹ̀bùn wo l' a hà lè fi wé Jésù?
Kò s' ọkan, kò s' ọkan;
Yóò hà kọ̀ fún wa, k' a n' ilé l' ọ̀run,
Kò jẹ́ kọ̀, kò jẹ́ kọ̀!

Jésù mọ̀ gbogbo ìdánwò wa,
Yóò tọ́jú wa títí d' òpin;
Kò s' ọ̀rẹ́ bí Jésù Onírẹ̀lè,
Kò s' ọ̀rẹ́, kò s' ọ̀rẹ́;