Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 507: Ẹnìkan Ń Bẹ T' Ó Fẹ́ràn Wa
One There Is Above All Others
Ẹnìkan ń bẹ t' ó fẹ́ràn wa,
A! Ó fẹ́ wa!
Ìfẹ́ Rẹ̀ jù t' ìyẹ̀kan lọ,
A! Ó fẹ́ wa!
Ọ̀rẹ́ ayé ń kọ wa sílẹ̀,
B' oní dùn, ọ̀la lè korò,
Ṣùgbọ́n Ọ̀rẹ́ yìí kò ń tàn ni,
A! Ó fẹ́ wa!
Ìyè ni fún wa b' a bá mọ On,
A! Ó fẹ́ wa!
Rò, b' a ti jẹ́ ni 'gbèsè tó,
A! Ó fẹ́ wa!
Ẹ̀jẹ̀ Rẹ̀ l' Ó sì fi rà wá,
Nín' àginjù l' Ó wá wa rí,
Ó sì mú wa wá s' àgbo Rẹ̀
A! Ó fẹ́ wa!
Ọ̀rẹ́ òdodo ni Jésù,
A! Ó fẹ́ wa!
Ó fẹ́ láti máa búkún wa,
A! Ó fẹ́ wa!
Ọkàn wa fẹ́ gbọ́ ohùn Rẹ̀
Ọkàn wa fẹ́ láti sún mọ́ Ọ,
Òun náà kò sì ní tàn wa jẹ
A! Ó fẹ́ wa!
Òun l' Ó jẹ́ k' a r' ìdáríjì
A! Ó fẹ́ wa!
Òun Ó lé ọ̀tá wa sẹ́hìn,
A! Ó fẹ́ wa!
Òun Ó pèsè 'bùkún fún wa,
Ire l' a ó máa rí títí,
Òun ó fi mú wa lọ s' ògo,
A! Ó fẹ́ wa!