Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 506: Mo Fẹ́ Kí N Dàbí Jésù
I Want To Be Like Jesus
Mo fẹ́ kí n dàbí Jésù,
Nínú ìwà pẹ̀lẹ́
Kò s' ẹni t' ó gbọ́ 'rọ̀ 'bínú
L' ẹnu Rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan rí.
Mo fẹ́ kí n dàbí Jésù
L' àdúrà 'gbà gbogbo;
Lórí òkè ni Òun nìkan
Lo padé Bàbá Rẹ̀.
Mo fẹ́ kí n dàbí Jésù,
Èmi kò rí i kà pé
Bí wọ́n ti kórìírà Rẹ̀ tó,
Ó ṣ' ẹnìkan níbi
Mo fẹ́ kí n dàbí Jésù
Nínú iṣẹ́ rere,
K' a lè wí nípa t' èmi pé,
"Ó ṣe wọn t' ó lè ṣe.
Mo fẹ́ kí n dàbí Jésù,
T' ó f' ìyọ̀nú wípé,
"Jẹ́ k' ọmọdé wá s' ọ̀dọ̀ mi"
Mo fẹ́ jẹ 'pè Rẹ̀.
Ṣùgbọ́n n kò dàbí Jésù,
Ó sì hàn gbangba bẹ́ẹ̀
Jésù fún mi l' oore-ọ̀fẹ́,
Ṣe mi kí n dàbí Rẹ̀.