Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 504: Yíká Or' Ìtẹ́ Ọlọ́run
Around The Throne Of God
Yíká or' ìtẹ́ Ọlọ́run,
Ẹgbẹ̀rún èwé wà,
Èwé t' a à dàrí ẹ̀ṣẹ̀ jì,
Àwọn ẹgbẹ́ mímọ́
Ń kọrin ògo, ògo, ògo,
Ń kọrin ògo, ògo, ògo.
Kíl' ó mú wọn dé ayé náà,
Ọ̀run t' ó ṣe mímọ́,
Níb' àlááfíà àt' ayọ̀,
Bí wọ́n ti ṣe dé 'bẹ̀?
Ń kọrin ògo, ògo, ògo,
Ń kọrin ògo, ògo, ògo.
'Tórí wọn, Jésù tà 'jẹ̀ Rẹ̀,
Láti k' ẹ̀ṣẹ̀ wọn lọ
A rí wọn nínú ẹ̀jẹ̀ náà,
Wọ́n di mímọ́ láùláù;
Ń kọrin ògo, ògo, ògo,
Ń kọrin ògo, ògo, ògo.
L' ayé wọn wá Olùgbàlà,
Wọ́n fẹ́ orúkọ Rẹ̀;
Nísìsìyí wọ́n r' ojú Rẹ̀
Wọ́n wà níwájú Rẹ̀;
Ń kọrin ògo, ògo, ògo,
Ń kọrin ògo, ògo, ògo.