Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 502: 'Gbà 'Wọn Ìyá Salem

When Mothers Of Salem

'Gbà 'wọn ìyá Salem'
Gb' ọmọ wọn tọ Jésù wá,
Àwọn ọm' -ẹ̀hìn Rẹ̀ lé wọn
Wí pé kí wọn máa lọ;
Ṣùgbọ́n kí wọn tó máa sá lọ.
Jésù rí wọn, Ó f' ayọ̀ pè,
“Jẹ́ kí àwọn ọmọ-wẹ́wẹ́ tọ Mi wá!”

Èm' ó tẹwọ́ gbà wọn,
N ó gbé wọn mọ́ra pẹ̀lú;
Èmi yóò jẹ́ Olùṣọ́ wọn
Ẹ má ṣe lé wọn lọ!
Bí wọ́n bá f' ọkàn wọn fún Mi,
Wọ́n yóò bá Mi gbé 'nú ògo;
Jẹ́ kí àwọn, ọmọ-wẹ́wẹ́ tọ Mi wá!

Olùgbàlà wa ṣeun
T' Ó tẹwọ́ gbà 'wọn 'mọ náà
Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ èwé ń bẹ tí
Kò gbọ́ oókọ Rẹ̀ rí.
Tí wọ́n kò ka Bíbélì rí
Níbi t' Olùgbàlà sọ,
“Jẹ́ kí àwọn ọmọ-wẹ́wẹ́ tọ Mi wá”

Láìpẹ́ kí kèfèrí
Tí ń bẹ ní gbogbo ayé
M' ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ṣe, kí wọn sì kọ
Òrìṣà wọn dà nù!
Jọ̀ọ́ tàn ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ sí wọn,
F' ara hàn b' Ọlọ́run ìfẹ́;
Kọ́ àwọn 'mọ-wẹ́wẹ́ láti tọ Ọ wá.