Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 500: Iná Kékeré L' A Ń Ṣe

We Are But Little Candles

Iná kékeré l' a ń ṣe,
Àwa lè tàn rọ́rọ́;
K' a f' ìmọ́lẹ̀ tín-ntín wa
Fi Olùgbàlà hàn,
Nígbà tí àwa bá ń sìn,
T' a sì ń mú 'fẹ́ Rẹ̀ ṣe,
'Tórí àwa fẹ́ràn Rẹ̀,
A sì ń fẹ́ ṣe 'fẹ́ Rẹ̀.

Ǹjẹ́ winni, winni, winni, winni,
B' a ti ń tàn rọ́rọ́;
Ìtànsán wa hàn yíká wa,
Lókè lódò, lókè lódò,
Kààkiri ní 'bi gbogbo
Báyìí l' àwa ń tàn.

Ìsọkúsọ oun 'bínú,
Burú púpọ̀púpọ̀;
'Tórí wọ́n ó pa 'ná wa,
'Tórí náà k' a ṣọ́ra,
Àtúntàn iná ṣòro,
Ṣùgbọ́n k' a gbìdánwò,
K' Ọlọ́run dàríjì wa,
K' Ó sì rán wa lọ́wọ́.

Ǹjẹ́ winni, winni, winni, winni,
B' a ti ń tàn rọ́rọ́;
Ìtànsán wa hàn yíká wa,
Lókè lódò, lókè lódò,
Kààkiri ní 'bi gbogbo
Báyìí l' àwa ń tàn.

Ẹkún wa yóò pa 'ná náà
'Tórí náà k' a múra,
Láti máa yọ n' gbà-gbogbo
K' a má ṣe rẹ̀wẹ̀sì,
Tór' Ẹlẹ́dàá fẹ́ràn wa,
Yóò tọ́ yóò sì kọ́ wa;
Ó sọ fún wa n' ọ̀rọ̀ Rẹ̀
Ohun t' ó yẹ k' a ṣe.

Ǹjẹ́ winni, winni, winni, winni,
B' a ti ń tàn rọ́rọ́;
Ìtànsán wa hàn yíká wa,
Lókè lódò, lókè lódò,
Kààkiri ní 'bi gbogbo
Báyìí l' àwa ń tàn.