Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 50: Ará Ẹ Jẹ́ K' Á Jumọ̀ Rìn

Brethren Let Us Walk Together

Ará ẹ jẹ́ k' á jumọ̀ rìn
N' ìfẹ́ oùn àlááfíà;
A ha lè ṣeṣe máa wí pé,
Kò tó k' àwọn ará jà?
Nínú 'rẹ̀pọ̀, nínú 'rẹ̀pọ̀,
L' ayọ̀ àt' ìfẹ́ pọ̀ sí i.

B' á tí ń rìn lọ s' ilé, jẹ́ k' á
Ran 'ra wa lọ́wọ́ l' ọ̀nà;
Ọ̀tá ha wà níbi gbogbo;
S' ọ̀nà gbogbo l' á dẹ́kun,
Iṣẹ́ wa ni, Iṣẹ́ wa ni,
K' á máa ran 'ra wa l' ẹ̀rù.

Nígbàt' á r' ohun Bàbá ṣe,
T' ó ti fi jí, t' ó ń' fi jí
Ará, kò tó k' àwa k' ó kọ́
Láti máa f' ìjà sílẹ̀?
Ká a mú u kúrò, K' á mú u kúrò
Ohun 'bá mú 'bínú wa.

K' á gb' ọmọnìkejì wa ga,
Jù bá a bá ti gbé 'ra wa;
Ká a fi kẹ́ẹ̀tà gbogbo sílẹ̀.
K' ọkàn wa sì kún fún 'fẹ́;
Yóò rọ wa, Yóò rọ wa,
Bá a wà n' ìrẹ̀pọ̀ l' ayé.