Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 5: Yìn Ọlọrun Ọba Wa

Praise God, Our King

Yìn Ọlọrun Ọba wa:
Ẹ gbé ohun ìyìn ga;
Àánú Rẹ̀ ó wà títí,
L' òdodo, dájúdájú.

Yìn Ín n' torí Ó dá oòrùn,
Tí ó ń ràn lójojúmọ́;
Àánú Rẹ̀ ó wà títí,
L' òdodo, dájúdájú.

Àti òṣùpá l' òru,
Tí ó ń tan mọ́lẹ́ jẹ́jẹ́;
Àánú Rẹ̀ ó wà títí,
L' òdodo, dájúdájú

Yìn In n' tor' Ó fún wa l'òjò
Láti mú 'rúgbìn dàgbà;
Àánú Rẹ̀ ó wà títí,
L' òdodo, dájúdájú

Ó si pasẹ fún oko
Láti so ẹ̀so rere;
Àanu Rẹ̀, ó wà títí,
L' òdodo, dájúdájú.

Yìn Ín fún ìkórè oko,
Tí Ó fi kún àka wa;
Àánú Rẹ̀ ó wà títí,
L' òdodo, dájúdájú.

Yìn Ín, f' óúnje t' ó ju yíí lọ̀,
Ẹ̀rí 'bùkún àilọpin,
Àánú Rẹ̀ ó wà títí,
L' òdodo, dájúdájú.

Ogo f' Ọba Olóore:
Ẹdá, ẹ kọrin ògo:
Ogo fúm Baba, Ọmọ,
Àt' Èmí Mẹ́tàlọ́kan.