Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 499: Nígbà Kan Àwọn 'Mọdé K' Orin

Long Ago The Children Sang

Nígbà kan àwọn 'mọdé k' orin
Ìyìn sí Jésù b' Ó ti ń g' ẹṣin lọ;
Hosana! Hosana!
Hosana l' òkè ọ̀run!

Orin 'yìn, orin 'yìn
Jẹ́ k' àwọn ọmọdé kọrin
Ìyìn wọn; Orin 'yìn orin 'yìn
Jésù fẹ́ gbọ́ orin wa.

B' ìgbà 'tíjọ́ Ó fẹ́ gb' orin wa,
Orin ìyìn sí Ọba wa ọ̀run;
Hosana! Hosana!
Hosana l' òkè ọ̀run!

Orin 'yìn, orin 'yìn
Jẹ́ k' àwọn ọmọdé kọrin
Ìyìn wọn; Orin 'yìn orin 'yìn
Jésù fẹ́ gbọ́ orin wa.

Nígbòòṣe a ó kọrin t' ó dùn,
Pẹ̀l' àwùjọ tó l' ògo, ta a gbàlà;
Hosana! Hosana!
Hosana l' òkè ọ̀run!

Orin 'yìn, orin 'yìn
Jẹ́ k' àwọn ọmọdé kọrin
Ìyìn wọn; Orin 'yìn orin 'yìn
Jésù fẹ́ gbọ́ orin wa.