Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 498: Àwọn Èwé Salẹmu
Children Of Jerusalem
Àwọn èwé Salẹmu
Kọrin 'yìn oókọ Jésù;
Àwa èwé t' ìsìyìí,
Jùmọ̀ yìn Olùgbàlà.
Gbọ́! gbọ́! gbọ́
B' àwọn èwé ti ń kọ,
Gbọ́! gbọ́! gbọ́
B' àwọn èwé ti ń kọ,
Ké Hosana, Ké Hosana
Ké Hosana s' Ọba wa.
A kọ́ wa k' a f' Olúwa,
K' a sì máa ka ọ̀rọ̀ Rẹ̀,
A f' ọ̀nà ọ̀run hàn wa;
Ògo ni fún Ọlọ́run
Gbọ́! gbọ́! gbọ́
B' àwọn èwé ti ń kọ,
Gbọ́! gbọ́! gbọ́
B' àwọn èwé ti ń kọ,
Ké Hosana, Ké Hosana
Ké Hosana s' Ọba wa.
K' olùkọ́, t' àgbà-t' èwé,
Jùmọ̀ gbé orin náà ga;
Lókè-lókè, k' ó máa hó,
Kí Hosana dé ọ̀run.
Gbọ́! gbọ́! gbọ́
B' àwọn èwé ti ń kọ,
Gbọ́! gbọ́! gbọ́
B' àwọn èwé ti ń kọ,
Ké Hosana, Ké Hosana
Ké Hosana s' Ọba wa.