Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 497: Ọ̀rẹ́ Kan Ń Bẹ Fún Ọmọdé

There's A Friend For Little Children

Ọ̀rẹ́ kan ń bẹ fún ọmọdé
Lókè ọ̀run lóhùn-ún;
Ọ̀rẹ́ tí kìí yípadà,
T' ìfẹ́ Rẹ̀ kò lè kú;
Kò dàbí ọ̀rẹ́ ayé,
Tí ń bajẹ́ l' ọdọọdún,
Orúkọ Rẹ̀ bí ọ̀rẹ́
Wọ fún-un nígbà-gbogbo.

Ìsimi kan ń bẹ f' ọmọdé
Lókè ọ̀run lóhùn-ún;
F' àwọn t' ó f' Olùgbàlà,
Tí ń ké Abba Bàbá,
Ìsimi lọ́wọ́ 'yọ̀nú;
L' ọ̀w' ẹ̀ṣẹ̀ àt' ewu;
Níbi t' àwọn ọmọdé
Yóò simi títí láé.

Ilé kan ń bẹ fún ọmọdé,
Lókè ọ̀run lóhùn-ún,
Níbi tí Jésù ń jọba,
Ilé àlááfíà!
Kò s' ilé t' ó jọ ọ l' ayé
T' a lè fi ṣàkàwé:
Ara rọ 'lúkúlúkú;
Ìrora náà d' òpin.

Adé kan ń bẹ fún ọmọdé
Lókè ọ̀run lóhùn-ún;
Ẹni t' ó bá ń wò Jésù
Yóò rí adé náà dé;
Adé t' ó l' ògo jùlọ,
Tí yóò fi fún gbogbo
Àwọn ọ̀rẹ́ Rẹ̀ l' ayé
Àwọn t' ó fẹ́ E níhìn-ín.