Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 495: Jésù, 'Ṣẹ́ Wà Fún Mi Bí

Master Hast Thou Work For Me?

Jésù, 'ṣẹ́ wà fún mi bí?
N ó f' ayọ̀ ṣiṣẹ́ fún Ọ;
Aláìlágbára l' èmi,
Bẹ́ẹ̀ mo fẹ́ wúlò fún Ọ;
B' ọwọ́ mi tilẹ̀ kéré
Síbẹ̀ n ó ṣiṣẹ́ fún Ọ.

Jésù 'ṣẹ́ wà fún mi bí?
N ó f' ayọ̀ ṣiṣẹ́ fún Ọ.

Jẹ́ kí n kọ́ nígb' èwé mi
Ẹ̀kọ́ láti 'nú 'wé Rẹ̀;
Jẹ́ kí n rìn ní ọ̀nà Rẹ̀
K' èmi sì mọ̀ ìfẹ́ Rẹ̀;
Mo fi ara mi fún Ọ,
Jẹ́ kí n sìn Ọ, Ọba mi!

Jésù 'ṣẹ́ wà fún mi bí?
N ó f' ayọ̀ ṣiṣẹ́ fún Ọ.

Jẹ́ kí n máa fún irúgbìn,
Jẹ́ kí n máa ṣe 'ṣẹ́ rere;
Fi 'fẹ́ 'rànwọ́ Rẹ̀ fún mi
Fún mi ní ìgbékẹ̀lé;
Mo mọ̀ pé 'wọ yóò kọ́ mi,
Bí n ó ti sìn Ọ níhìn.

Jésù 'ṣẹ́ wà fún mi bí?
N ó f' ayọ̀ ṣiṣẹ́ fún Ọ.